Jẹ́nẹ́sísì 29:30-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Jákọ́bù sì bá Rákélì náà lòpọ̀. Ó sì fẹ́ràn Rákélì ju Líà lọ, ó sì ṣiṣẹ́ sin Lábánì fún ọdún méje mìíràn.

31. Nígbà tí Ọlọ́run sì ri pé, Jákọ́bù kò fẹ́ràn Líà, ó sí i ni inú ṣùgbọ́n Rákélì yàgàn.

32. Líà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Rúbẹ́nì, nítorí ó wí pé, “Nítorí Ọlọ́run ti mọ ìpọ́njú mi, dájúdájú, ọkọ mi yóò fẹ́ràn mi báyìí.”

33. Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Símónì, wí pé “Nítorí tí Olúwa ti gbọ́ pé a kò fẹ́ràn mi, ó sì fi èyí fún mi pẹ̀lú.”

Jẹ́nẹ́sísì 29