Jẹ́nẹ́sísì 28:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Kí Ọlọ́run kí ó fún ìwọ àti irú ọmọ rẹ ní ìre tí ó sú fún Ábúráhámù, kí ìwọ kí ó le gba ilẹ̀ níbi tí a ti ń ṣe àtìpó yìí, ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún Ábúráhámù.”

5. Bẹ́ẹ̀ ni Ísáákì sì rán Jákọ́bù lọ. Ó sì lọ sí Padani-Árámù, lọ́dọ̀ Lábánì ọmọ Bétúélì, ará Árámíà, tí í ṣe arákùnrin Rèbékà ìyá Jákọ́bù àti Ísọ̀.

6. Nígbà tí Ísọ̀ gbọ pé, Ísáákì ti ṣúre fún Jákọ́bù, ó sì ti ran Jákọ́bù lọ sí Padani-Árámù láti fẹ́ aya níbẹ̀ àti pé nígbà tí ó ṣúre fún un, ó kìlọ̀ fun un pé, kò gbọdọ̀ fẹ́ nínú àwọn ọmọbìnrin Kénánì

7. àti pé, Jákọ́bù ti gbọ́ràn sí ìyá àti baba rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ti lọ sí Padani-Árámù.

8. Nígbà náà ni Ísọ̀ mọ bí Ísáákì baba rẹ ti kórìíra àwọn ọmọbìnrin Kénánì tó.

Jẹ́nẹ́sísì 28