37. Ísáákì sì dá Ísọ̀ lóhùn pé, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ àti àwọn ìbátan rẹ ni mo fi ṣe ìránṣẹ́ fún-un, àti oúnjẹ àti wáìnì ni mo ti fi lé e lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, kí ni ó tún kù tí ǹ bá tún fún ọ báyìí ọmọ mi?”
38. Ísọ̀ sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Ṣe ìre kan ṣoṣo ni ìwọ ní lẹ́nu ni baba mi?, Ṣúre fún èmi náà, baba mi.” Ísọ̀ sì sunkún kíkankíkan.
39. Ísáákì bàbá rẹ̀ sì dá a lóhùn pé,“Ibùjòkòó rẹyóò jìnnà sí ọ̀rá ilẹ̀,àti sí ìrì ọ̀run láti òkè wá.
40. Nípa idà ni ìwọ yóò máa gbé,ìwọ yóò sì máa sin àbúrò rẹ,ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, nígbà tí ìwọ bá di alágbáraìwọ yóò já àjàgà rẹ̀-kúrò lọ́rùn rẹìwọ yóò sì di òmìnira.”
41. Ísọ̀ sì kóríra Jákọ́bù nítorí ìre tí baba rẹ̀ sú fún un, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Baba mi ṣáà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú, nígbà náà ni èmi ó pa Jákọ́bù, arákùnrin mi.”
42. Nígbà tí Rèbékà sì gbọ́ ohun tí Ísọ̀ àkọ́bí rẹ̀ wí, ó sì ránṣẹ́ sí Jákọ́bù, ó sì wí fun un pé, “Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ ń tu ara rẹ̀ nínú pẹ̀lú èrò àti pa ọ́.
43. Nítorí náà ọmọ mi, ṣe ohun tí èmi yóò sọ fún ọ: Ṣá lọ sọ́dọ̀ Lábánì ẹ̀gbọ́n mi ní Háránì.