1. Ábúráhámù sì tún fẹ́ aya mìíràn, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kétúrà.
2. Ó sì bí Ṣímúránì, Jókíṣánì, Médánì, Mídíánì, Ísíbákù, àti Ṣúà
3. Jókíṣánì ni baba Ṣébà àti Dédánì, àwọn ìran Dédánì ni àwọn ara Áṣúrímù, Létúsì àti Léúmínù.
4. Àwọn ọmọ Mídíánì ni Éfánì, Éférì, Ánókù, Ábídà àti Élídà. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Kétúrà.
5. Ábúráhámù sì fi ohun gbogbo tí ó ní fún Ísáákì.
6. Ṣùgbọ́n kí o tó kú, ó fún àwọn ọmọ tí àwọn àlè rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn, ó sì lé wọn jáde lọ fún Ísáákì ọmọ rẹ sí ilẹ̀ ìlà oòrùn.