Jẹ́nẹ́sísì 23:15-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. “Gbọ́ tèmi Olúwa mi, irínwó (400) òsùwọ̀n owó fàdákà ni ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n kín ni ìyẹn já mọ láàrin àwa méjèèjì? Ṣáà sin òkú ù rẹ.”

16. Ábúráhámù sì gba ohun tí Éfúróni wí, ó sì wọn iye owó fàdákà náà lójú gbogbo ènìyàn: irínwó owó idẹ fàdákà gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n oníṣòwò ayé ìgbà náà.

17. Báyìí ni ilẹ̀ Éfúrónì tí ó wà ni Mákípélà nítòòsí Mámúrè-ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ àti gbogbo igi tí ó wà nínú ilẹ̀ náà ni a ṣe ètò rẹ̀ dájú,

18. bí ohun-ìní fún Ábúráhámù níwájú gbogbo ará Hétì tí ó wá sí ẹnu ibodè ìlú náà.

19. Lẹ́yìn náà ni Ábúráhámù sin aya rẹ̀ Sárà sínú ihò àpáta ní ilẹ̀ Mákípélà nítòòsí Mámúrè (tí í ṣe Ébúrónì) ní ilẹ̀ Kénánì.

20. Ilẹ̀ náà àti ihò-àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni àwọn ará Hítì fi fún Ábúráhámù gẹ́gẹ́ bí ohun ìní títí láé bí ilẹ̀ ìsìnkú fún àwọn òkú tí ó bá kú fun un.

Jẹ́nẹ́sísì 23