Jẹ́nẹ́sísì 19:35-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún fún baba wọn ní ọtí mu yó ni alẹ́ ọjọ́ náà, èyí àbúrò náà sì wọlé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a lò pọ̀, kò sì tún mọ ìgbà tí ó wọlé ṣùn ti òun tàbí ìgbà tí ó dìde.

36. Àwọn ọmọbìnrin Lọ́tì méjèèjì sì lóyún fún baba wọn.

37. Èyí ẹ̀gbọ́n sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Móábù. Òun ni baba ńlá àwọn ará Móábù lónìí.

38. Èyí àbúrò náà sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹni-Ámì. Òun ni baba ńlá àwọn ará Ámónì lónìí.

Jẹ́nẹ́sísì 19