Jẹ́nẹ́sísì 18:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Ábúráhámù pé, “Kín ló dé tí Ṣárà fi rẹ́rìn-ín tí ó sì wí pé, ‘Èmi yóò ha bímọ nítòótọ́, nígbà tí mo di ẹni ogbó tan?’

14. Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí ó sòro jù fún Olúwa? Èmi ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí àmọ́dún, Ṣárà yóò si bí ọmọkùnrin.”

15. Ẹ̀rù sì ba Ṣárà, ó sì sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín.Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún-un pé, “Dájúdájú ìwọ rẹ́rín-ín.”

Jẹ́nẹ́sísì 18