6. Ábúrámù dáhùn pé, “Ìwọ ló ni ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣe ohunkóhun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ sí i.” Nígbà náà ni Ṣáráì fi ìyà jẹ ẹ́, ó sì sá lọ.
7. Ańgẹ́lì Olúwa sì rí Ágáì ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi ní ijù, ìsun omi tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀na tí ó lọ sí Ṣúrì.
8. Ó sì wí pé, “Hágárì, ìránṣẹ́ Ṣáráì, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo sì ni ìwọ ń lọ?”Ó sì dáhùn pé, “Mo ń sá lọ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá mi Ṣáráì ni.”
9. Ańgẹ́lì Olúwa sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ kí o sì tẹríba fún un.”