Jẹ́nẹ́sísì 13:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun-ìní wọn pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, débi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀.

7. Èdè àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn darandaran Ábúrámù àti ti Lọ́tì. Àwọn ará a Kénánì àti àwọn ará Pérísítì sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà.

8. Ábúrámù sì wí fún Lọ́tì pé, “Mo fẹ́ kí a fòpin sí èdè àìyedè tí ó wà láàrin èmi àti ìwọ àti láàrin àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí ni wá.

9. Gbogbo ilẹ̀ ha kọ́ nìyí níwájú rẹ? Jẹ́ kí a pínyà. Bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi yóò lọ sí apá òsì, bí ó sì ṣe òsì ni ìwo lọ, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún.”

Jẹ́nẹ́sísì 13