Jẹ́nẹ́sísì 13:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ábúrámù sì gòkè láti Éjíbítì lọ sí Nẹ́gẹ́fù ní ìhà gúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọ́tì pẹ̀lú.

2. Ábúrámù sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi, ní ẹran-ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà.

3. Láti Gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Bẹ́tẹ́lì, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú ri lágbedeméjì Bẹ́tẹ́lì àti Áì.

Jẹ́nẹ́sísì 13