Jẹ́nẹ́sísì 12:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nítorí náà, sọ pé, arábìnrin mi ni ìwọ, wọn yóò sì ṣe mí dáradára, a ó sì dá ẹ̀mí mi sí nítorí tìrẹ.”

14. Nígbà tí Ábúrámù dé Éjíbítì, àwọn ará Éjíbítì ri i pé aya rẹ̀ rẹwà gidigidi.

15. Nígbà tí àwọn ìjòyè Fáráò sì rí i, wọ́n ròyìn rẹ̀ níwájú u Fáráò, Wọ́n sì mú un lọ sí ààfin,

16. Ó sì kẹ́ Ábúrámù dáradára nítorí Ṣáráì, Ábúrámù sì ní àgùntàn àti màlúù, akọ àti abo, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, pẹ̀lú u ràkunmí.

Jẹ́nẹ́sísì 12