Jẹ́nẹ́sísì 11:10-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Wọ̀nyí ni ìran ṢémùỌdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣémù pé ọgọ́rùn-ún ọdún (100) ni ó bí Áfákísádì.

11. Lẹ́yìn tí ó bí Áfákísádì, ó tún wà láàyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

12. Nígbà tí Áfákísádì pé ọdún marùndínlógójì (35) ni ó bí Ṣélà.

13. Ó sì wà láàyè fún ọdún mẹ́talénírínwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣélà, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn.

14. Nígbà tí Ṣélà pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Ébérì.

Jẹ́nẹ́sísì 11