Jákọ́bù 1:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jákọ́bù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti ti Jésù Kírísítì Olúwa,Sí àwọn ẹ̀yà méjìlá tí ó fọ́n káà kiri, orílẹ̀-èdè.Àlàáfíà.

2. Ẹ̀yin ara mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdẹwo ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀;

3. Nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìdẹwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣisẹ́ sùúrù.

4. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò se aláìní ohunkóhun.

Jákọ́bù 1