9. Ó dá mi lóhùn pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì àti Júdà pọ gan an ni; ilé wọn kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti àìsòótọ́. Wọ́n ní, ‘Olúwa tí kọ ilẹ̀ náà sílẹ̀; Olúwa kò sì rí wa.’
10. Nítorí náà, n kò ní wò wọ́n pẹ̀lú àánú n kò sì ní dá wọn sí, ṣùgbọ́n N ó dá ohun tí wọ́n ti ṣe padà sórí wọn.”
11. Ọkùnrin aláṣọ funfun pẹ̀lú ohun ìkọ̀wé lẹ́gbẹ́ rẹ̀ sì wá jábọ̀ pé, “Mo ti ṣe ohun tí o pa láṣẹ.”