5. N ó tẹ́ òkú àwọn ará Ísírẹ́lì síwájú òrìsà wọn n ó sì fọ́n egungun wọn yí pẹpẹ wọn ká.
6. Gbogbo ibi tí ẹ ń gbé àti àwọn ibi gíga yín ni yóò di píparun, gbogbo pẹpẹ yín ni yóò di ahoro, àwọn òrìṣà yín yóò di fífọ́ túútúú, àwọn pẹpẹ tùràrí yín ni a ó gé lulẹ̀, gbogbo iṣẹ́ yín yóò parẹ́.
7. Àwọn ènìyàn yín yóò ṣubú láàrin yín, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.
8. “ ‘Ṣùgbọ́n n ó dá àwọn kan sí nítorí pé díẹ̀ nínú yín ni yóò bọ́ lọ́wọ́ idà, nígbà tí a bá fọ́n yín ká sí gbogbo ilẹ̀ àti orílẹ̀ èdè.
9. Àwọn ti ó bọ́ nínú yin yóò sì ránti mi láàrin àwọn orílẹ́-èdè níbi tí wọn o dì wọ́n ní ìgbèkùn lọ, nítorí ti mo ti tọ́ ọkàn àgbèrè wọn ti o ti lọ kúrò, lọ́dọ̀ mi àti pẹ̀lú ojú wọn, ti n sàgbérè lọ sọ́dọ̀ òrìsà wọn, wọn o si sú ara wọn nítorí ìwà ibi ti wọn ti hù nínú gbogbo ìríra wọn.