24. Òun yóò sì pèsè éfà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ jíjẹ. Éfà kan fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti éfà kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú hini òróró kan fún éfà kan.
25. “ ‘Láàárin ọjọ́ méje àṣè náà, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹẹdógún oṣù kéje, òun yóò tún pèsè nǹkan bí ti tẹ́lẹ̀, fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú òróró.