Ísíkẹ́lì 43:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ẹ ni láti mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí ẹ sì fi sórí ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà lórí pẹpẹ, àti lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ìjòkòó náà àti sí gbogbo etí rẹ̀ yípo, ìwọ yóò sì sọ pẹpẹ di mímọ́, ìwọ yóò sì ṣe ètùtù rẹ̀.

21. Ìwọ gbọdọ̀ mú akọ màlúù fún ìrékọjá, ìwọ yóò sì sun ún ní apá ibi tí a ṣàmì sí ní agbègbè ilé Ọlọ́run ní ìta ibi mímọ́.

22. “Ní ọjọ́ kejì ìwọ yóò fi ewúrẹ́, òbúkọ aláìlábàwọ́n fún ẹbọ ẹsẹ, a sì gbọdọ̀ sọ pẹpẹ di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ́ di mímọ́ pẹ̀lú akọ màlúù.

Ísíkẹ́lì 43