Ísíkẹ́lì 4:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nítorí mo fi iye ọdún tí wọ́n fi ṣẹ̀ fún ọ gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ tí ìwọ yóò lò. Nítorí náà, ìwọ yóò ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390).

6. “Tí o bá parí èyí, tún fi ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún dùbúlẹ̀ kí o sì ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Júdà fún ogójì (40) ọjọ́, nítorí pé ọjọ́ kan ló dúró fún ọdún kan.

7. Dojú kọ ibùdó ogun Jérúsálẹ́mù, na ọwọ́ rẹ sí i, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìlú náà.

8. Èmi yóò dè ọ́ ní okùn débi pé ìwọ kò ní í le yírapadà láti ìhà ọ̀tún sí ìhà òsì títí tí ọjọ́ ìgbógun tì rẹ yóò fi pé.

9. “Mú ọkà bàbà àti àlìkámà, erèé àti lẹ́ńtìlì, jéró àti ẹwẹ; fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe àkàrà tí ìwọ yóò máa jẹ nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀ fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá.

Ísíkẹ́lì 4