10. Wọn kò ní nílo láti kó igi jọ láti inú pápá, tàbí gé e láti inú igbó, nítorí pé wọ́n yóò lé òhun ìjà ogun bi epo ìdáná. Wọn yóò sì kógun àwọn tí ó ṣe ìgárá sí wọn, wọn yóò sì bo ilé àwọn tí ó bo ilé wọn, ni Olúwa Ọba tẹnumọ́.
11. “ ‘Ní ọjọ́ náà èmi yóò sì fi ibi ìsìnkú fún Gógì ní Ísírẹ́lì, ni àfonífojì àwọn ti ó rìn ìrìnàjò lọ sí agbègbè ilà òòrùn òkun. Yóò di ojú ọ̀nà àwọn arìnrìn àjò, nítorí Gógì àti gbogbo ìjọ rẹ̀ ni àwa yóò sin síbẹ̀. Nítorí náà, a óò pè é ní àfonífojì tí Ámónì Gógì.
12. “ ‘Fún oṣù méje ní ilé Ísírẹ́lì yóò fi máa sìn wọ́n láti ṣe àfọ̀mọ́ ilẹ̀ náà.
13. Gbogbo ènìyàn ilẹ náà yóò sìn wọ́n, ọjọ́ tí a yìn mi lógo yóò jẹ́ ọjọ́ ìrántí, ní Olúwa Ọba wí.
14. “ ‘Wọn yóò gbà àwọn ènìyàn ṣíṣẹ́ lóòrèkóórè láti ṣe àfọ̀mọ́ náà. Ọ̀pọ̀ yóò lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ní àfikún pẹ̀lú wọn, àwọn tó kù yóò sìn àwọn tí ó kú lórí ilẹ̀: Ní ìparí oṣù kéje wọn yóò bẹ̀rẹ̀ wíwá kiri wọn.
15. Bí wọ́n n lọ káàkiri ilẹ̀ náà ọ̀kan nínú wọn rí egungun ènìyàn, oun yóò gbé àmì ńlá kalẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ títí àwọn asìnkú yóò fi sìn ín ní àfonífojì Ámónì Gógì.