14. “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, ṣọtẹ́lẹ̀ kí ó sì ṣọ fún Gógì: ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ní ọjọ́ náà, nígbà tí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì ń gbé ní àìléwu, ìwọ kì yóò ha ṣe àkíyèsí rẹ̀?
15. Ìwọ yóò wá láti ààyè rẹ ní jìnnàjìnnà àríwá, ìwọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ, gbogbo wọn yóò sì gun ẹsìn ìjọ ńlá, jagunjagun alágbára.
16. Ìwọ yóò tẹ̀síwájú ní ìlòdì sí àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀. Ni àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ìwọ Gógì, èmi yóò mú ọ wá ní ìlòdì sí ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀ èdè lè mọ̀ mi nígbà tí mo bá fí ara hàn ni mímọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ojú wọn.
17. “ ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ìwọ ha kọ́ ni mo ṣọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìgbà ìṣáájú láti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi ti Ísírẹ́lì? Ní ìgbà náà wọ́n ṣọtẹ́lẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún pé èmi yóò mú ọ lòdì sí wọn.
18. Èyí ni ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà: Nígbà tí Gógì bá kọlu ilẹ̀ Ísírẹ́lì, gbígbóná ibínú mi yóò ru sókè, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
19. Ní ìtara mi àti ní gbígbóná ìbínú mi, Mo tẹnumọ́-ọn pé; ní àsìkò náà ilẹ̀ mímì tíi ó lágbára ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì yóò ṣẹlẹ̀.
20. Ẹja inú òkun, àwọn ẹyẹ òfuurufú, àwọn ẹranko igbó, àti gbogbo ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀ yóò wárìrì fún ìfarahàn mi. A óò yí òkè gíga po, àwọn bèbè òkúta ni àwa yóò fọ́ sí wẹ́wẹ́, gbogbo ògiri ni yóò wó palẹ̀.