Ísíkẹ́lì 34:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ́ mi wá:

2. “Ọmọ ènìyàn, fí àsọtẹ́lẹ̀ tako olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì; sọ tẹ́lẹ̀ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ègbé ni fún olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì tí ó ń tọ́jú ara wọn nìkan! Ṣé ó dára kí olùṣọ́ àgùntàn ṣaláì tọ́jú agbo ẹran?

3. Ìwọ jẹ wàrà. O sì wọ aṣọ olówùú sí ara rẹ, o sì ń pa ẹran tí ó wù ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò tọ́jú agbo ẹran.

Ísíkẹ́lì 34