11. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:
12. “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tírè kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹrẹ ìjẹ́pípé náào kún fún ọgbọ́n,o sì pé ní ẹwà
13. Ìwọ ti wà ní Édẹ́nì, ọgbà Ọlọ́run;onírúurú òkúta iyebíye ni ìbora rẹ;sárídù, tópásì àti díámọ́ndì, bérílì oníkì,àti jásípérì, sáfírè, émérálídìàti káríbúnkílì, àti wúràìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dàláti ara wúrà,ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.
14. A fi àmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù,torí èyí ni mo fi yàn ọ́.Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run;ìwọ rìn ni àárin òkúta amúbína,
15. Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹláti ọjọ́ tí a ti dá ọtítí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ.