11. Àwọn ènìyàn Árífádì àti Hélékìwà lórí odi rẹ yíká;àti àwọn akọni Gámádì,wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ.Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ;wọn ti mú ẹwà rẹ pé.
12. “ ‘Táṣíṣì ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin tanúnganran àti òjé fún ọjà títà rẹ̀.
13. “ ‘Àwọn ará Gíríkì, Túbálì, Jáfánì àti Méṣékì, ṣòwò pẹ̀lú rẹ: wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàsípààrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ.