Ísíkẹ́lì 23:29-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Wọn yóò fìyà jẹ ọ́ pẹ̀lú ìkórìíra, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tí o ṣiṣẹ́ fún lọ. Wọn yóò fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò goloto, ìtìjú iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ ni yóò farahàn. Ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti ìdàrúdàpọ̀ rẹ

30. ni ó mú èyí wá sórí rẹ, nítorí tí ìwọ ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si orílẹ̀ èdè, o sì fi àwọn òrìṣà rẹ́ ara rẹ jẹ.

31. Ìwọ ti rin ọ̀nà ti ẹ̀gbọ́n rẹ rìn; Èmi yóò sì fi aago rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.

Ísíkẹ́lì 23