8. Ṣùgbọ́n ìwọ, ọmọ ènìyàn, gbọ́ ohun tí mo ń sọ fún ọ. Má se ṣọ̀tẹ̀ bí i ti ìdílé ọlọ́tẹ̀; la ẹnu rẹ kí o sì jẹ ohun tí mo fún ọ.”
9. Mo sì wò, mo sì rí ọwọ́ kan tí a nà sí mi. Ìwé tí a ká sì wà níbẹ̀,
10. ó sì tú ìwé náà fún mi. Ní ojú àti ẹ̀yìn ìwé náà ni a kọ ohùnréré ẹkún, ọ̀fọ̀ àti ègún sí.