14. Èmi yóò wó ògiri tí ẹ fi amọ̀ àìpò rẹ́, èyí tí ẹ fi ẹfun kùn lulẹ̀ débi pé ìpìlẹ̀ rẹ yóò hàn jáde. Nígbà ti odi náà wó palẹ̀, a ó sì run yín sínú rẹ̀, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.
15. Báyìí ni N ó ṣe lo ìbínú mi lórí odi yìí àti àwọn to fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ, tí wọ́n sì fi ẹfun kùn ún. N ó sì sọ fún yín pé, “Kò sí odi mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tó rẹ́ ẹ náà kò sí mọ́;
16. Àwọn wòlíì Ísírẹ́lì tí ń sọtẹ́lẹ̀ nípa àlàáfíà nígbà ti kò sì àlàáfíà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí.” ’
17. “Nísinsin yìí, ọmọ ènìyàn, dojú kọ àwọn ọmọbìnrin ènìyàn rẹ tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ láti inú èrò ọkàn wọn, sọtẹ́lẹ̀ sí wọn