Ísíkẹ́lì 12:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. N ó ta àwọ̀n mi lé e lórí, yóò sì kó sínú okùn, N ó sì mú lọ sí Bábílónì, ní ilẹ̀ Kádíyà, ṣùgbọ́n kò ní fojú rí ilẹ̀ náà ibẹ̀ ni yóò kú sí.

14. Gbogbo àwọn tó yí i ká láti ràn án lọ́wọ́ (opá ìtẹ̀lẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀) ni N ó túká sí afẹ́fẹ́, n ó sì tún fi idà lé wọn kiri.

15. “Wọn ó sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo bá tú wọn ká láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo sì fọ́n wọn ká sí ilẹ̀ káàkiri.

Ísíkẹ́lì 12