12. Ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nítorí pé ẹ̀yin kò tẹ̀lé àṣẹ mi ẹ kò sì pa òfin mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ ti hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ orílẹ̀ èdè tó yí yín ká.”
13. Bí mo ṣe ń sọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́, Pélátíà ọmọ Bénáyà kú. Mo sì dojúbolẹ̀, mo sì kígbe sókè pé, “Áà! Olúwa, Ọlọ́run! Ṣé o fẹ́ pa ìyókù Ísírẹ́lì run pátapáta ni?”
14. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá:
15. “Ọmọ ènìyàn, àwọn arákùnrin rẹ, àní àwọn ará rẹ, àwọn ọkùnrin nínú ìbátan rẹ, àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì pátapáta, ni àwọn ará Jérúsálẹ́mù ti wí fún pé, ‘Ẹ jìnnà sí Olúwa, àwa ni a fi ilẹ̀ yìí fún yín ní ìní.’
16. “Nítorí náà, sọ fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn káàkiri orílẹ̀ èdè, síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, n ó jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn níbi tí wọ́n lọ.’