12. Olúkúlùkù wọn ń lọ tààrà. Níbikíbi tí èmi bá ń lọ, ni àwọn náà ń lọ, láì wẹ̀yìn bí wọ́n ti ń lọ.
13. Ìrísí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí dàbí ẹyin iná tí ń jó tàbí bí i iná tọ́ọ̀sì. Iná tó ń jó ń lọ sókè lọ sódò láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè; iná yìí mọ́lẹ̀ rokoṣo, ó sì ń bù yẹ̀rì yẹ̀rì jáde lára rẹ̀.
14. Àwọn ẹ̀dá alààyè yìí sì ń sáré lọ sókè lọ sódò bí i ìtànsán àrá.
15. Bí mo ti ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè yìí, mo rí kẹ̀kẹ́ ní ilẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí pẹ̀lú ojú rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.
16. Àpèjúwe àti ìrísí àwọn kẹ̀kẹ́ náà nìyìí: kẹ̀kẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rí bákan náà, wọ́n sì ń tàn yinrin yinrin bí i kírísólétì, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kẹ̀kẹ́ yìí rí bí i ìgbà tí a fi kẹ̀kẹ́ bọ kẹ̀kẹ́ nínú.