11. Gbogbo àwọn ańgẹ́lì sì dúró yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn àgbà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ká, wọn wólẹ̀ wọn si dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà wọ́n sì sin Ọlọ́run.
12. Wí pe:“Àmín!Ìbùkún, àti ògo,àti ọgbọ́n, àti ọpẹ́, àti ọlá,àti agbára àti ipá fún Ọlọ́run wa láé àti láéláé!Àmín!”
13. Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà si dáhùn, ó bi mí pé, “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí a wọ ni aṣọ funfun? Níbo ni wọn sì ti wá?”
14. Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.”Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú Ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà.