11. Mo sì rí ọ̀run sí sílẹ̀, sì wò ó, ẹsin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòótọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun.
12. Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkárarẹ̀.
13. A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀: a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
14. Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọrùn tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ̀yìn lórí ẹ̀sin funfun.
15. Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi ṣá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn:” ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè.
16. Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:ỌBA ÀWỌN ỌBA ÀTI Olúwa ÀWỌN Olúwa
17. Mo sì rí ańgẹ́lì kan dúró nínú òòrùn; ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé: “Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè-ńlá Ọlọ́run;