6. Mo sì rí obìnrin náà mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ajẹ́rìí ikú Jésù ní àmuyó.Nígbà tí mo sì rí i, ẹnu yà mi gidigidi.
7. Ańgẹ́lì sì wí fún mi pé, “Nítorí kí ni ẹnu ṣe yà ọ́? Èmi ó sọ ti ìjìnlẹ̀ obìnrin náà fún ọ, àti ti ẹranko tí ó gùn, ti ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá.
8. Ẹranko tí ìwọ ri nì, o ti wà, kò sì sí mọ́: Yóò sì ti inú ọ̀gbun gòkè wá, yóò sì lọ sínú ìwé iye láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, nígbà tí wọn ń wò ẹranko tí o ti wà, tí kò sì sí mọ́, tí ó sì ń bọ̀ wá.
9. “Níhìn-ín ni ìtumọ̀ tí o ní ọgbọ́n wà. Orí méje ni òkè ńlá méje ni, lórí èyí tí obìnrin náà jókòó.
10. Ọba méje sì ní wọn: àwọn márùn-ún ṣubú, ọ̀kan ń bẹ, ọ̀kan ìyókù kò sì tí ì dé; nígbà tí ó bá sì dé, yóò dúró fún ìgbà kúkurú.
11. Ẹranko tí ó sì ti wà, tí kò sì sí, òun náà sì ni ìkẹjọ, ó sì ti inú àwọn méje náà wá, ó sì lọ sí ìparun.