Ìfihàn 16:13-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Mo sì rí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ mẹ́ta bí ọ̀pọ̀lọ́, wọ́n ti ẹnu dírágónì náà àti ẹnu ẹranko náà àti ẹnu wòlíì èké náà jáde wá.

14. Nítorí ẹ̀mí èṣù ni wọ́n, tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu, àwọn tí ń jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé, láti gbá wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olúdàmarè.

15. “Kíyèsí i; ń bọ̀ bi olè, ìbùkún ni fún ẹni tí ń sọ́nà, tí ó sì ń pa aṣọ rẹ̀ mọ́, kí ó mà bàá rìn ni ìhóhò, wọn a sì rí ìtìjú rẹ̀.”

16. Ó sì gbá wọn jọ́ sí ìbikan tí a ń pè ní Ámágédónì ní èdè Hébérù.

17. Èkeje si tú ìgo tírẹ̀ sí ojú ọ̀run; ohùn ńlá kan sì ti inú tẹ́ḿpìlì jáde láti ibi ìtẹ́, wí pé, “Ó parí!”

18. Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá sì ṣẹ̀, irú èyí tí kò sẹ̀ ri láti ìgbà tí ènìyàn ti wà lórí ilẹ̀, irú ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá bẹ́ẹ̀, tí ó sì lágbára tóbẹ́ẹ̀.

19. Ìlú ńlá náà sì pín sí ipa mẹ́ta, àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú: Bábílónì ńlá sì wá sí ìrántí níwájú Ọlọ́run, láti fi ago ọtí wáìnì ti ìrunú ìbínú rẹ̀ fún un.

20. Olúkúlùkù erekúṣu sì sálọ, a kò sì ri àwọn òkè ńlá mọ́.

Ìfihàn 16