Ìṣe Àwọn Àpósítélì 7:58-60 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

58. wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ́ ní òkúta; àwọn ẹlẹ́rìí sì fi aṣọ wọn lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọmọkùnrin kan tí a ń pè ní Sọ́ọ̀lù.

59. Bí wọ́n ti ń sọ ọ́ ní òkúta, Sítéfánù gbàdúrà wí pé, “Jésù Olúwa, gba ẹ̀mi mi.”

60. Nígbà náà ni ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó kígbe sókè pé, “Olúwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn ní ọrùn.” Nígbà ti ó sì wí èyí tán, ó sùn lọ.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 7