Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Bí ó bá ṣe pé a ń wádìí wa lónì ní tí iṣẹ́ rere ti a ṣe lára abirùn náà, bí a ti ṣe mú ọkùnrin yìí láradá,

10. Kí èyí yé gbogbo yín àti gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì pé, ni orúkọ Jésù Kírísítì ti Násárétì, tí ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, tí Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, nípa rẹ̀ ni ọkùnrin yìí fi dúró níwájú yín ni ara dídá-ṣáṣá.

11. Èyí ni“ ‘òkúta tí a ti ọwọ́ ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,tí ó sì di pàtàkì igun ilé.’

12. Kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlomìíràn; nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run ti a fifún ni nínú ènìyàn, nípa èyí tí a lè fi gbà wá là.”

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4