Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4:16-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Wí pé, “Kí ni a ó ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí? Ní ti pé iṣẹ́ àmì tí ó dájú tí ọwọ́ wọn ṣe, ó hàn gbangba fún gbogbo àwọn tí ń gbé Jerúsálémù; àwa kò sì lè ṣe èyí.

17. Ṣùgbọ́n kí ó má ba à tàn kálẹ̀ ṣíwájú mọ́ láàrin àwọn ènìyàn, ẹ jẹ́ kí a kìlọ̀ fún wọn pé, láti ìsinsin yìí lọ kí wọn má ṣe fi orúkọ yìí sọ̀rọ̀ sí ẹnikẹ́ni mọ́.”

18. Wọ́n sì pè wọ́n, wọ́n pàsẹ fún wọn, kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ tàbí kọ́ni rárá mọ́ ní orúkọ Jésù.

19. Ṣùgbọ́n Pétérù àti Jòhánù dáhùn, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá tọ́ lójú Ọlọ́run láti gbọ́ tiyín ju ti Ọlọ́run lọ ẹ gbà á rò.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4