20. Ǹjẹ́ nítorí ọ̀ràn yìí ni mo ṣe ránṣẹ́ pè yín, láti rí yín àti láti bá yín sọ̀rọ̀ nítorí pé, nítorí ìrètí Ísírẹ́lì ni a ṣe fi ẹ̀wọ̀n yìí dè mí.”
21. Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò rí ìwé gbà láti Jùdíà nítorí rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan nínú àwọn arákùnrin tí ó ti ibẹ̀ wá kò ròyìn, tàbí kí ó sọ̀rọ̀ ibi kan sí ọ.
22. Ṣùgbọ́n àwa ń fẹ́ gbọ́ lẹ́nu rẹ ohun tí ìwọ rò nítorí bí ó ṣe ti ìsìn ìyapa yìí ní, àwa mọ̀ pé, níbi gbogbo ni a ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.”
23. Àwọn fi ẹnu kò lórí ọjọ́ tí wọn yóò se ìpàdé pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó tọ̀ ọ́ wa ni ilé àgbàwọ̀ rẹ̀; àwọn ẹni tí òun sọ àsọyé ọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún, ó ń yí wọn padà nípa ti Jésù láti inú òfin Mósè àti àwọn wòlíì, láti òwúrọ̀ títí ó fi di àṣálẹ́.