10. Èyi ni mo sì ṣe ni Jerúsálémù. Pẹ̀lú àṣẹ tí mo tí gba lọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, mo sọ àwọn púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn mímọ́ sí inú túbú, nígbà tí wọ́n sí ń pa wọ́n, mo ní ohùn sí i.
11. Nígbà púpọ̀ ni mo ń fi ìyà jẹ wọ́n láti inú ṣínágọ́gù dé inú ṣínágọ́gù, mo ń fi tipá mú wọn láti sọ ọ̀rọ̀-òdì. Mo sọ̀rọ̀ lòdì ṣí wọn gidigidi, kódà mo wá wọn lọ sí ìlú àjèjì láti ṣe inúnibíni sí wọn.
12. “Nínú irú ìrìnàjò yìí ní mo ń bá lọ sí Dámásíkù pẹ̀lú ọlá àti àṣẹ ikọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.
13. Ni ọ̀ṣángangan, ìwọ ọba, bí mo ti wà ní ojú ọ̀nà, mo rí ìmọ́lẹ̀ kan láti ọ̀run wá, tí ó mọ́lẹ̀ ju òòrùn lọ, ó mọ́lẹ̀ yí mi ká, àti àwọn tí ń bá mi lọ sì àjò.