5. Ẹ jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn olórí yín bá mi sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ìdí ẹ̀sùn tí ẹ fi sun ọkùnrin náà múlẹ̀ níbẹ̀, bí ó bá ní ohun búburú kan tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀.”
6. Lẹ́yìn tí ó sì ti gbé níwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ tàbí mẹ́wàá pẹ̀lú wọn, ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sì Kesaríà, ni ọjọ́ kéjì ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, ó sì pàṣẹ pé ki a mú Pọ́ọ̀lù wá síwájú òun.
7. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì dé, àwọn Júù tí o tí Jerúsálémù ṣọ̀kalẹ̀ wá dúró yì í ká, wọ́n ǹ ka ọ̀ràn púpọ̀ tí ó sì burú sí Pọ́ọ̀lù lọ́rùn, tí wọn kò lè làdí rẹ̀.
8. Pọ́ọ̀lù si wí tí ẹnu rẹ̀ pé, “Èmi kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ kan sì òfin àwọn Júù, tàbí tẹ́ḿpílì, tàbí sí Késárì”