40. Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀ mìíràn ni ó fi ń kìlọ̀ tí ó sì ń fi ń rọ̀ wọ́n wí pé, “Ẹ gba ara yín là lọ́wọ́ ìran àrékérekè yìí.”
41. Nítorí náà àwọn tí ó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ a bamítíìsì wọn, lọ́jọ́ náà a sì kà ìwọn ẹgbẹ̀rùn mẹ́ta ọkàn kún wọn.
42. Wọ́n sì dúró ṣinṣin nínú ẹ̀kọ́ àwọn àpósítélì, àti ní ìdàpọ̀, ní bíbu àkàrà àti nínú àdúrà.
43. Ẹ̀rù sí ba gbogbo ọkàn; iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì púpọ̀ ni a ti ọwọ́ àwọn àpósítélì ṣe.
44. Gbogbo àwọn tí ó sì gbàgbọ́ wà ni ibìkan, wọn ní ohun gbogbo sọ́kàn;