Ìṣe Àwọn Àpósítélì 14:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sí ṣe, ni Ìkóníónì, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà júmọ́ wọ inú sínágọ́gù àwọn Júù lọ, wọ́n sì sọ̀rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti àwọn aláìkọlà gbàgbọ́,

2. Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbàgbọ́ Júù rú ọkàn àwọn aláìkọlà sókè, wọ́n sì mú wọn ni ọkàn ìkorò sí àwọn arákùnrin náà.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 14