44. Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, gbogbo ìlú sí fẹ́rẹ̀ pejọ́ tan lati gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
45. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, wọ́n kún fún owú, wọ́n ń sọ̀rọ̀-òdì sí ohun ti Pọ́ọ̀lù ń sọ.
46. Pọ́ọ̀lù àti Básébà sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, “Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà.
47. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti paṣẹ̀ fún wa pé:“ ‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà,kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’ ”
48. Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́.