Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13:39-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mósè.

40. Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé:

41. “ ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù;nítorí èmi ń ṣe iṣẹ́ kan lọ́jọ́ yín,iṣẹ́ tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́bí ẹnìkan tilẹ̀ ròyìn rẹ̀ fún yín.’ ”

42. Bí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sì ti ń jáde láti inú sínàgọ́gù, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13