Ìṣe Àwọn Àpósítélì 10:29-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Nítorí náà ni mo sì ṣe wá ní àìjiyàn, bí a ti ránṣẹ́ pè mi: ǹjẹ́ mo bèèrè, nítorí kín ní ẹ̀yin ṣe ránṣẹ́ pè mi?”

30. Kọ̀nẹ́líù sì dáhùn pé, “Ní ìjẹrin, mo ń ṣe àdúrà wákàtí kẹ́sàn-án ọjọ́ ni ilé mi títí di idayìí, sì wò ó, ọkùnrin kan aláṣọ, àlà dúró níwájú mi.

31. Ó sì wí pé, ‘Kọ̀nélíù, a gbọ́ àdúrà rẹ, ọrẹ-àánú rẹ̀ sì wà ni ìrántí níwájú Ọlọ́run.

32. Ǹjẹ́ ránsẹ́ lọ sí Jópà, kí ó sì pe Símónì wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Pétérù; ó wọ̀ ní ilé Símónì aláwọ léti òkun: nígbà ti ó bá dé, ẹni yóò sọ̀rọ̀ fún ọ.’

33. Nítorí náà ni mo sì ṣe ránṣẹ́ sì ọ lójúkan náà, ìwọ sì ṣeun tí ó fi wá. Gbogbo wa pé níwájú Ọlọ́run nísinsìnyìí, láti gbọ́ ohun gbogbo, ti a pàṣẹ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.”

34. Pétérù sì ya ẹnu rẹ, ó sì wí pé, “Nítòótọ́ mo wòye pé, Ọlọ́run kì í ṣe ojusajú ènìyàn.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 10