13. “Nígbà ti Éfúráímù ri àìsàn rẹ̀,tí Júdà sì rí ojú egbò rẹ̀ni Éfúráímù bá tọ ará Síríà lọ,ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́ṣùgbọ́n kò le è wò ó sànbẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná
14. Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Éfúráímù,bí i kìnnìún ńlá sí ilé Júdà.Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ;Èmi ó gbé wọn lọ, láì sí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.
15. Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mitítí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀biwọn yóò sì wá ojú minínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”