Hágáì 2:21-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. “Sọ fún Sérúbábélì baálẹ̀ Júdà pé èmi yóò mi àwọn ọ̀run àti ayé.

22. Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, Èmi yóò sì pa agbára àwọn aláìkọlà run; Èmi yóò sì dojú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun dé, àti àwọn tí ń gùn wọ́n; ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́sin yóò ṣubú; olúkúlùkù nípa idà arákùnrin rẹ̀.”

23. Olúwa àwọn wí pé, “Ní ọjọ́ náà, àwọn ọmọ-ogun iwọ ìránṣẹ́ mi Sérúbábélì ọmọ Séítíélì, Èmi yóò mú ọ, Èmi yóò sì sọ ọ di bí òrùka èdìdì mi, nítorí mo ti yan ọ, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

Hágáì 2