Hábákúkù 1:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú òkun,bí àwọn ẹ̀dá inú òkun tí wọn ko ni alákòóso

15. Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn ṣókèó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n-ńlá rẹ̀;nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú.

16. Nítorí náà, ó rúbọ sí àwọ̀n rẹ̀,ó sì ń ṣun tùràrí fún àwọ̀n-ńlá rẹ̀nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fí ń gbé ní ìgbádùntí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú.

17. Ǹjẹ́ wọn yóò ha máa pá àwọ̀n wọn mọ́ ní òfìfo bí,tí wọn yóò sí pa orílẹ̀-èdè run láìsí àánú?

Hábákúkù 1