Fílípì 1:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín:

4. Nínú gbogbo àdúrà mi fún-un yín, èmi ń fi ayọ̀ gbàdúrà,

5. nítorí ìdàpọ̀ yín nínú ìyìn rere láti ọjọ́ kìn-ín-ni wá títí di ìsinsinyìí.

6. Ohun kan yìí ṣáà dá mi lójú pé, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín, yóò ṣe àṣepé rẹ̀ títí di ọjọ́ Jésù Kírísítì:

Fílípì 1