Fílímónì 1:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Oore-Ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jésù Kírísítì.

4. Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi,

5. nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jésù Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́.

6. Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábàápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ̀ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọ-ingbọ-in, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kírísítì wá.

Fílímónì 1