1. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tán, àwọn olórí tọ̀ mí wá wọ́n sì wí pé, Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, ti ó fi mọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, kò tì í ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn agbègbè tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra bí i ti àwọn ọmọ Kénánì, Hítì, Pérísì, Jébúsì, Ámónì, Móábù Éjíbítì àti Ámórì.
2. Wọ́n ti fẹ́ lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún ara wọn àti fún àwọn ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí aya, wọ́n ti da ìran mímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ti ó wà ní àyíká wọn. Àwọn olórí àti àwọn ìjòyè ta àwọn ènìyàn tó kù yọ nínú hihu ìwà “Àìsòótọ́.”